الطارق

At-Tariq

Sūrah 86 · ti Mọkkah · āyah 17 · Ètò ìsọ̀kalẹ̀: 36

Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀

Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Allāhu) fi sánmọ̀ àti Tọ̄riƙ búra.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ Tọ̄riƙ?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌràwọ̀ tí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ń tàn ròrò (ní alẹ́ ni).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKò sí ẹ̀mí kan àfi kí ẹ̀ṣọ́ kan wà fún un (nínú àwọn mọlāika).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, kí ènìyàn wòye sí ohun tí A fi ṣẹ̀dá rẹ̀.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n ṣẹ̀dá rẹ̀ láti inú omi tó ń tú jáde kọ̀ọ́kọ̀ọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ ń jáde láti ààrin ìbàdí ọkùnrin àti àwọn ẹfọ́nhà igbá-àyà obìnrin.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Allāhu ni Alágbára lóri ìdápadà rẹ̀
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniní ọjọ́ tí wọ́n máa ṣe àyẹ̀wò àwọn (iṣẹ́) àṣepamọ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà náà, kò níí sí agbára tàbí alárànṣe kan fún un.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu fi sánmọ̀ tó ń rọ òjò ní ọdọọdún búra.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ tún fi ilẹ̀ tó ń sán kànkàn (fún híhùjáde èso) búra.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú al-Ƙur’ān ni ọ̀rọ̀-ìpínyà (láààrin òdodo àti irọ́).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKì í sì ṣe àwàdà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú wọ́n ń déte gan-an.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÈmi náà sì ń déte gan-an.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, lọ́ra fún àwọn aláìgbàgbọ́. Lọ́ wọn lára sẹ́ fún ìgbà díẹ̀.