الأعلى
Al-A'la
Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀
Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢàfọ̀mọ́ fún orúkọ Olúwa rẹ, Ẹni gíga jùlọ.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸni tí Ó dá ẹ̀dá. Ó sì ṣe (oríkèé-ríkèé rẹ̀) ní dọ́gbadọ́gba.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸni tí Ó yan kádàrá (fún ẹ̀dá). Ó sì tọ́ ọ sọ́nà.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸni tí Ó mú koríko tútù hù jáde,
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sì sọ ọ́ di gbígbẹ tó dúdú.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwa yóò máa ké (al-Ƙur’ān) fún ọ. Ìwọ kò sì níí gbàgbé.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀyàfi ohun tí Allāhu bá fẹ́.[1] Dájúdájú Ó mọ gban̄gba àti ohun tó pamọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwa yó sì ṣe iṣẹ́ rere ní ìrọ̀rùn fún ọ.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ṣèrántí ní àyè tí ìrántí ti wúlò.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸni tí ó máa páyà (Allāhu) máa lo ìrántí.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOlórí-burúkú sì máa takété sí i.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Òun sì ni) ẹni tí ó máa wọ inú Iná tó tóbi.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, kò níí kú sínú rẹ̀, kò sì níí ṣẹ̀mí (àlàáfíà).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ẹni tí ó bá ṣe àfọ̀mọ́ (ẹ̀sìn rẹ̀) ti jèrè.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sì rántí orúkọ Olúwa rẹ̀, ó sì kírun.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniRárá, ńṣe l’ẹ̀ ń gbé àjùlọ fún ìṣẹ̀mí ayé.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniỌ̀run sì lóore jùlọ, ó sì máa wà títí láéláé.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú èyí wà nínú àwọn tákàǹdá àkọ́kọ́,
- Abu Rahimah Mikael Aykyunitákàdá (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm àti (Ànábì) Mūsā.