الغاشية
Al-Ghashiyah
Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀
Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢebí ọ̀rọ̀ nípa ohun tó máa bo ẹ̀dá mọ́lẹ̀ ti dé ọ̀dọ̀ rẹ?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn ojú kan yóò wálẹ̀ (ní ti ìyẹpẹrẹ) ní ọjọ́ yẹn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n ṣe iṣẹ́ àṣekúdórógbó (ni nílé ayé).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sì máa wọ inú Iná tó gbóná janjan (ní ọ̀run).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sì máa fún (wọn) ní omi ìṣẹ́lẹ̀rú gbígbóná mu.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKò sí oúnjẹ kan fún wọn àyàfi igi ẹlẹ́gùn-ún gbígbẹ.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKò níí mú wọn sanra. Kò sì níí rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ebi.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn ojú kan yó sì kún fún ìgbádùn ní ọjọ́ yẹn
- Abu Rahimah Mikael Aykyuninítorí pé (ó) yọ́nú sí (ẹ̀san) iṣẹ́ rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ó máa) wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra gíga.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọn kò níí gbọ́ ìsọkúsọ nínú rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOmi ìṣẹ́lẹ̀rú tó ń ṣàn wà nínú rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn ibùsùn tí wọ́n gbé sókè wà nínú rẹ̀,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti àwọn ife ìmumi tí wọ́n gbé kalẹ̀ (sí àrọ́wọ́tó wọn),
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti àwọn ìrọ̀rí tí wọ́n tò sí ẹ̀gbẹ́ ara wọn,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti àwọn ìtẹ́ àtẹ́ẹ̀ká.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ṣé wọn kò wòye sí ràkúnmí, bí A ti ṣẹ̀dá rẹ̀ ni;
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti sánmọ̀, bí A ti ṣe gbé e sókè;
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti àpáta, bí A ti ṣe gbé e nàró (sínú ilẹ̀);
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti ilẹ̀, bí A ti ṣe tẹ́ ẹ sílẹ̀ pẹrẹsẹ?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ṣèrántí. Ìwọ kúkú ni olùṣèràntí.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÌwọ kì í ṣe ajẹni-nípá lórí wọn
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàfi ẹni tí ó bá pẹ̀yìndà (sí òdodo), tí ó sì ṣàì gbàgbọ́.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu sì máa jẹ ẹ́ níyà tó tóbi jùlọ.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ọ̀dọ̀ Wa ni àbọ̀ wọn wà.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, dájúdájú Àwa l’A máa ṣe ìṣírò-iṣẹ́ wọn.