الفجر
Al-Fajr
Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀
Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
- Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu fi àfẹ̀mọ́júmọ́ búra.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ tún fi àwọn òru mẹ́wàá kan búra.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ tún fi n̄ǹkan tí eéjì ń pín geerege àti n̄ǹkan tí eéjì kò pín geerege búra.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ tún fi òru nígbà tí ó bá dé búra.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniǸjẹ́ ìbúra wà nínú ìyẹn fún onílàákàyè?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé o kò wòye sí bí Olúwa rẹ ti ṣe ọ̀rọ̀ ará ‘Ād,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(ìyẹn àwọn ìran) ’Irọm, àwọn òmìrán,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàwọn tí A kò dá irú wọn mọ́ sínú ìlú?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti àwọn Thamūd tí wọ́n gbẹ́ (ilé ìgbé) sínú àpáta nínú àfonúfojì,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniàti Fir‘aon eléèkàn (ìyà)?
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Àwọn wọ̀nyí ni) àwọn tó tayọ ẹnu-ààlà nínú ìlú.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sì ṣe ìbàjẹ́ púpọ̀ sínú rẹ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOlúwa rẹ sì rọ̀jò ìyà lé wọn lórí.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú Olúwa rẹ wà ní ibùṣọ́ (iṣẹ́ ẹ̀dá).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ní ti ènìyàn, nígbà tí Olúwa rẹ̀ bá dán an wò, tí Ó pọ́n ọn lé, tí Ó sì ṣe ìdẹ̀ra fún un, nígbà náà ó máa wí pé: “Olúwa mi ti pọ́n mi lé.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢùgbọ́n nígbà tí Ó bá dán an wò, tí Ó gán arísìkí rẹ̀ lé e lọ́wọ́, nígbà náà ó máa wí pé: “Olúwa mi ti yẹpẹrẹ mi.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniRárá, kò rí bẹ́ẹ̀, bí kò ṣe pé, ẹ̀yin kò ṣàpọ́nlé ọmọ-òrukàn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé ẹ̀yin kò gbẹra yín lóǹgbẹ láti fún mẹ̀kúnnù ní oúnjẹ.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸ tún ń jẹ ogún ní ìjẹkújẹ.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé ẹ nífẹ̀ẹ́ sí dúkìá ní ìfẹ́ púpọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniRárá, (kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀). Nígbà tí wọ́n bá mi ilẹ̀ tìtì ní mímì tìtì (tó rún wómúwómú, tí kò sí kòtò, tí kò sí gelemọ),
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(tí) Olúwa rẹ dé pẹ̀lú àwọn mọlāika ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ọ̀wọ̀ọ̀wọ́,
- Abu Rahimah Mikael Aykyuniní ọjọ́ yẹn ni wọ́n máa mú iná Jahanamọ wá. Ní ọjọ́ yẹn, ènìyàn yóò rántí (ọ̀rọ̀ ara rẹ̀). Báwo sì ni ìrántí náà ṣe lè wúlò fún un!
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ máa wí pé: “Yéè, èmi ìbá ti ti (iṣẹ́ rere) síwájú fún ìṣẹ̀mí mi.”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ọjọ́ yẹn, ẹnì kan kò lè fi ìyà jẹ (ẹ̀dá) bí irú ìyà (tí) Allāhu (yóò fi jẹ ẹ́).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniẸnì kan kò sì lè de (ẹ̀dá) ní ìgbèkùn bí irú ìgbèkùn (tí) Allāhu (yóò fi dè é).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÌwọ ẹ̀mí olùfọ̀kànbalẹ̀,
- Abu Rahimah Mikael Aykyunipadà sí ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ ní olùyọ́nú, ẹni ìyọ́nú.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, wọlé sáààrin àwọn ẹrúsìn Mi.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ inú Ọgbà Ìdẹ̀ra Mi.