البلد
Al-Balad
Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀
Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÈmi (Allāhu) ń fi ìlú yìí[1] búra.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÌwọ sì ní ẹ̀tọ́ sí ìlú yìí (láti jagun nínú rẹ̀).[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÈmi (Allāhu) ń fi òbí àti ohun tó bí búra.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn sínú ìṣòro.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé ó ń lérò pé ẹnì kan kò ní agbára lórí òun ni?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ (sì) ń wí pé: “Èmi ti bàná dúkìá ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ (láti fi tako Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -)”
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé ó ń lérò pé ẹnì kan kò rí òun ni?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé A kò ṣe ojú méjì fún un?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti ahọ́n pẹ̀lú ètè méjì (tí A ṣe fún un)?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniA sì fi ọ̀nà méjì mọ̀ ọ́n.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKò sì lọ rin ojú-ọ̀nà orí àpáta tó ṣòroó gùn fún ìgbàlà ẹ̀mí níbi Iná!
- Abu Rahimah Mikael AykyuniKí sì ni ó mú ọ mọ ohun tó ń jẹ́ ojú-ọ̀nà orí àpáta tó ṣòroó gùn fún ìgbàlà ẹ̀mí?
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Òhun ni) títú ẹrú sílẹ̀ lóko ẹrú.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTàbí fífún ènìyàn ní oúnjẹ ní ọjọ́ ebi.
- Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ẹ lè fún) ọmọ-òrukàn nínú ẹbí,
- Abu Rahimah Mikael Aykyunitàbí mẹ̀kúnnù tí kò ní gá tí kò ní go (olòṣì paraku).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, kí ó wà nínú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ń gbara wọn níyànjú sùúrù ṣíṣe, tí wọ́n sì tún ń gbara wọn níyànjú àánú ṣíṣe.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn wọ̀nyẹn ni èrò ọwọ́ ọ̀tún.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀwọn tó sì ṣàì gbàgbọ́ nínú àwọn āyah Wa, àwọn ni èrò ọwọ́ òsì.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n máa ti àwọn ìlẹ̀kùn Iná pa mọ́ wọn lórí pátápátá.