الشمس

Ash-Shams

Sūrah 91 · ti Mọkkah · āyah 15 · Ètò ìsọ̀kalẹ̀: 26

Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀

Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu fi òòrùn àti ìyálẹ̀ta rẹ̀ búra.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ tún fi òṣùpá nígbà tí ó bá (yọ) tẹ̀lé (òòrùn) búra.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ tún fi ọ̀sán nígbà tí ó bá mú ìmọ́lẹ̀ bá òkùnkùn òru búra.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ tún fi alẹ́ nígbà tí ó bá bo ọ̀sán mọ́lẹ̀ búra.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ tún fi sánmọ̀ àti Ẹni tí Ó mọ ọ́n[1] búra?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ tún fi ilẹ̀ àti Ẹni tí Ó tẹ́ ẹ kalẹ̀ pẹrẹsẹ búra.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ tún fi ẹ̀mí (ènìyàn) àti Ẹni tí Ó ṣe (oríkèé rẹ̀) dọ́gba búra.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sì fi ẹ̀ṣẹ̀ (tí ẹ̀mí lè dá) àti ìbẹ̀rù rẹ̀ mọ̀ ọ́n.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸnikẹ́ni tí ó bá ṣe àfọ̀mọ́ (ẹ̀mí ara) rẹ̀ (níbi ẹ̀ṣẹ̀), ó mà ti jèrè.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniẸnikẹ́ni tí ó bá fi (ìwà ẹ̀ṣẹ̀) ba ẹ̀mí (ara) rẹ̀ jẹ́, ó mà ti pàdánù.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÌjọ Thamūd pe òdodo ní irọ́ nípa ìtayọ ẹnu-ààlà wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Rántí) nígbà tí ẹni tí orí rẹ̀ burú jùlọ nínú wọn sáré dìde (láti gún ràkúnmí pa).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNígbà náà, Òjíṣẹ́ Allāhu sọ fún wọn pé: “(Ẹ fi) abo ràkúnmí Allāhu àti omi rẹ̀ (sílẹ̀).”
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n pè é ní òpùrọ́. Wọ́n sì gún (ràkúnmí) pa. Nítorí náà, Olúwa wọn pa wọ́n rẹ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ó sì fi ìparun náà kárí wọn.
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(Ẹni tó gún ràkúnmí pa) kò sì páyà ìkángun ọ̀rọ̀ wọn.