الليل

Al-Layl

Sūrah 92 · ti Mọkkah · āyah 21 · Ètò ìsọ̀kalẹ̀: 9

Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀

Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu fi alẹ́ nígbà tí (ilẹ̀) bá ṣú búra.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ tún fi ọ̀sán nígbà tí (ọ̀sán) bá pọ́n búra.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ tún fi Ẹni tí Ó dá akọ àti abo búra.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni iṣẹ́ yín.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ti ẹni tí ó bá tọrẹ, tí ó sì bẹ̀rù (Allāhu),
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(tí) ó tún pe ẹ̀san rere (Ọgbà Ìdẹ̀ra) ní òdodo,
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA sì máa ṣe iṣẹ́ rere ní ìrọ̀rùn fún un.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ti ẹni tí ó bá yahun, tí ó sì rí ara rẹ̀ lẹ́ni tó rọrọ̀ tayọ ẹ̀san ọ̀run,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuni(tí) ó tún pe ẹ̀san rere (Ọgbà Ìdẹ̀ra) ní irọ́,
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA sì máa ṣe iṣẹ́ aburú ní ìrọ̀rùn fún un.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDúkìá rẹ̀ kò sì níí rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀ nígbà tí ó bá parun, tí ó já bọ́ (sínú Iná).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú tiWa ni (láti ṣàlàyé) ìmọ̀nà.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniÀti pé dájúdájú tiWa ni ọ̀run àti ayé.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, Mo ti fi Iná tó ń jò fòfò kìlọ̀ fún yín.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKò sí ẹni tí ó máa wọ inú rẹ̀ àfi olórí burúkú,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniẹni tí ó pe òdodo ní irọ́, tí ó sì kẹ̀yìn sí i.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniWọ́n sì máa gbé (Iná) jìnnà sí olùbẹ̀rù (Allāhu),
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyuniẹni tó ń fi dúkìá rẹ̀ tọrẹ, tí ó ń ṣàfọ̀mọ́ (rẹ̀).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniKò sì sí oore ìdẹ̀ra kan tí (ó ní lọ́kàn) láti gbà ní ẹ̀san ní ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyunibí kò ṣe pé láti fi wá ojú rere Olúwa rẹ̀, Ẹni Gíga jùlọ.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniLáìpẹ́ ó sì máa yọ́nú (sí ẹ̀san rere rẹ̀).