الضحى
Ad-Duhaa
Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀
Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
- Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu fi ìyálẹ̀ta búra.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ tún fi alẹ́ nígbà tí (ilẹ̀) bá ṣú búra.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniOlúwa rẹ kò pa ọ́ tì, kò sì bínú sí ọ.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ọ̀run lóore fún ọ ju ayé.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú láìpẹ́ Olúwa rẹ máa fún ọ ní (oore púpọ̀ ní ọ̀run). Nítorí náà, o sì máa yọ́nú sí i.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé (Allāhu) kò rí ọ ní ọmọ-òrukàn ni? Ó sì fún ọ ní ibùgbé.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ sì rí ọ ní aláìmọ̀nà (ìyẹn ṣíwájú ìsọ̀kalẹ̀ ìmísí). Ó sì fi ọ̀nà mọ̀ ọ́.[1]
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ tún rí ọ ní aláìní, Ó sì rọ̀ ọ́ lọ́rọ̀.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, ní ti ọmọ-òrukàn, má ṣe jẹ gàba (lé e lórí).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ti alágbe, má sì ṣe jágbe (mọ́ ọn).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniNí ti ìdẹ̀ra Olúwa rẹ, sọ ọ́ jáde.