الشرح

Ash-Sharh

Sūrah 94 · ti Mọkkah · āyah 8 · Ètò ìsọ̀kalẹ̀: 12

Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀

Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.

بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé A kò ṣípayá igbá-àyà rẹ fún ọ bí?
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA sì gbé ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kúrò lọ́rùn rẹ,
  1. Abu Rahimah Mikael Aykyunièyí tí ó wọ̀ ọ́ lọ́rùn.[1]
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniA sì gbé ìrántí orúkọ rẹ ga fún ọ.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, dájúdájú ìdẹ̀kùn wà lẹ́yìn ìnira.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú ìdẹ̀kùn wà lẹ́yìn ìnira sẹ́.
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniNítorí náà, nígbà tí o bá bùṣe (lórí ohun tí ó jẹmọ́ táyé), gbìyànjú (dáadáa lórí ìjọ́sìn).
  1. Abu Rahimah Mikael AykyuniỌ̀dọ̀ Olúwa rẹ sì ni kí o ṣojú kòkòrò oore sí.