التين
At-Tin
Kíkọ
Àwọn ìtúmọ̀
Tẹ ọ̀rọ̀ Lárúbáwá kan láti rí kíkà rẹ̀, ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbòǹgbò rẹ̀.
بِسْمِ ٱللَّهِ ٱلرَّحْمَٰنِ ٱلرَّحِيمِ
- Abu Rahimah Mikael AykyuniAllāhu fi èso tīn àti èso zaetūn búra.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ tún fi àpáta Sīnīn búra.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÓ tún fi ìlú ìfàyàbalẹ̀ yìí búra.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniDájúdájú A ṣẹ̀dá ènìyàn pẹ̀lú ìrísí tó dára jùlọ.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniLẹ́yìn náà, A máa dá a padà sí ìsàlẹ̀ pátápátá (nínú Iná).
- Abu Rahimah Mikael AykyuniÀyàfi àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n sì ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Nítorí náà, ẹ̀san tí kò níí pin (tí kò níí pẹ̀dín) ń bẹ fún wọn.
- Abu Rahimah Mikael AykyuniTa l’ó tún ń pè ọ́ ní òpùrọ́ nípa Ọjọ́ ẹ̀san lẹ́yìn (ọ̀rọ̀ yìí)?
- Abu Rahimah Mikael AykyuniṢé Allāhu kọ́ ni Ẹni t’Ó mọ ẹ̀jọ́ dá jùlọ nínú àwọn adájọ́ ni?